Native Bible

Judges 8:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n dáhùn pé, “Tayọ̀tayọ̀ ni àwa yóò fi wọ́n sílẹ̀.” Wọ́n tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan sì ń sọ yẹtí kọ̀ọ̀kan tí ó kàn wọ́n láti ibi ìkógun síbẹ̀.

Judges 8:25 in English

Judges 8:25 · Berean Standard Bible

“We will give them gladly,” they replied. So they spread out a garment, and each man threw an earring from his plunder onto it.

Context

23Ṣùgbọ́n Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Èmi kì yóò jẹ ọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ mi kì yóò jẹ ọba lórí yín. Olúwa ni yóò jẹ ọba lórí yín.” 24Gideoni sì wí pé, “Mo ní ẹ̀bẹ̀ kan tí mo fẹ́ bẹ̀ yín kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín fún mi ní yẹtí kọ̀ọ̀kan láti inú ohun ti ó kàn yín láti inú ìkógun.” (Àṣà àwọn ará Iṣmaeli ni láti máa fi yẹtí wúrà sétí.) 25Wọ́n dáhùn pé, “Tayọ̀tayọ̀ ni àwa yóò fi wọ́n sílẹ̀.” Wọ́n tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan sì ń sọ yẹtí kọ̀ọ̀kan tí ó kàn wọ́n láti ibi ìkógun síbẹ̀. 26Ìwọ̀n òrùka wúrà tí ó béèrè fún tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán (1,700) ìwọ̀n ṣékélì, láìka àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti ohun sísorọ̀ tí ó wà lára ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn àti aṣọ elése àlùkò tí àwọn ọba Midiani ń wọ̀ tàbí àwọn ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọrùn àwọn ìbákasẹ wọn. 27Gideoni fi àwọn wúrà náà ṣe efodu èyí tí ó gbé kalẹ̀ ní Ofira ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli sì sọ ara wọn di àgbèrè nípa sínsin-ín ní ibẹ̀. Ó sì di ìdẹ̀kùn fún Gideoni àti ìdílé rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.