Onidajọ 8:12
Judges 8:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Seba àti Salmunna, àwọn ọba Midiani méjèèjì sá, ṣùgbọ́n Gideoni lépa wọn ó sì mú wọn, ó run gbogbo ogun wọn.
Judges 8:12 in English
Judges 8:12 · Berean Standard Bible
When Zebah and Zalmunna fled, Gideon pursued and captured these two kings of Midian, routing their entire army.
Context
10Ní àsìkò náà Seba àti Salmunna wà ní Karkori pẹ̀lú ọmọ-ogun wọn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) ọkùnrin, àwọn wọ̀nyí ni ó ṣẹ́kù nínú gbogbo ogun àwọn ènìyàn apá ìlà-oòrùn, nítorí ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) ọkùnrin tí ó fi idà jà ti kú ní ojú ogun. 11Gideoni gba ọ̀nà tí àwọn darandaran máa ń rìn ní apá ìhà ìlà-oòrùn Noba àti Jogbeha ó sì kọjú ogun sí àwọn ọmọ-ogun náà nítorí wọ́n ti túra sílẹ̀. 12Seba àti Salmunna, àwọn ọba Midiani méjèèjì sá, ṣùgbọ́n Gideoni lépa wọn ó sì mú wọn, ó run gbogbo ogun wọn. 13Gideoni ọmọ Joaṣi gba ọ̀nà ìgòkè Heresi padà sẹ́yìn láti ojú ogun. 14Ó mú ọ̀dọ́mọkùnrin kan ará Sukkoti, ó sì béèrè àwọn ìbéèrè ní ọwọ́ rẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì kọ orúkọ àwọn ìjòyè Sukkoti mẹ́tàdínlọ́gọ́rin fún un tí wọ́n jẹ́ àgbàgbà ìlú náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.