Onidajọ 7:22
Judges 7:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì fun fèrè wọn, Olúwa sì yí ojú idà ọkùnrin kọ̀ọ̀kan padà sí ẹnìkejì rẹ̀ àti sí gbogbo ogun wọn. Àwọn ọmọ-ogun sì sá títí dé Beti-Sitta ní ọ̀nà Serera títí lọ dé ìpínlẹ̀ Abeli-Mehola ní ẹ̀bá Tabbati.
Judges 7:22 in English
Judges 7:22 · Berean Standard Bible
And when the three hundred rams’ horns sounded, the LORD set all the men in the camp against one another with their swords. The army fled to Beth-shittah toward Zererah * as far as the border of Abel-meholah near Tabbath.
Context
20Àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fun fèrè wọn, wọ́n tún fọ́ àwọn ìkòkò wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n mú àwọn fìtílà iná wọn ní ọwọ́ òsì wọn àti fèrè tí wọ́n ń fun ní ọwọ́ ọ̀tún wọn. Wọ́n pariwo hé è pé, “Idà kan fún Olúwa àti fún Gideoni!” 21Nígbà tí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan dúró ní ipò rẹ̀ yí ibùdó àwọn Midiani ká, gbogbo àwọn ọmọ-ogun Midiani ń sá káàkiri, wọ́n ń pariwo bí wọ́n ṣe ń sálọ. 22Nígbà tí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì fun fèrè wọn, Olúwa sì yí ojú idà ọkùnrin kọ̀ọ̀kan padà sí ẹnìkejì rẹ̀ àti sí gbogbo ogun wọn. Àwọn ọmọ-ogun sì sá títí dé Beti-Sitta ní ọ̀nà Serera títí lọ dé ìpínlẹ̀ Abeli-Mehola ní ẹ̀bá Tabbati. 23Gbogbo àwọn ọmọ-ogun Israẹli láti ẹ̀yà Naftali, Aṣeri àti gbogbo Manase ni Gideoni ránṣẹ́ si, wọ́n wá wọ́n sì lé àwọn ará Midiani. 24Gideoni tún ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè Efraimu wí pé, “Ẹ jáde wá bá àwọn ará Midiani jà, kí ẹ tètè gba àwọn omi Jordani títí dé Beti-Bara kí wọ́n tó dé bẹ̀.”
Báyìí ni a ṣe pe gbogbo ọkùnrin ológun Efraimu jáde tí wọ́n sì gba gbogbo àwọn à bá wọ odò Jordani títí dé Beti-Bara.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.