Onidajọ 5:3
Judges 5:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọba! Ẹ fetí yín sílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ-aládé! Èmi yóò kọrin sí Olúwa, èmi yóò kọrin ìyìn sí Olúwa: Ọlọ́run Israẹli.
Judges 5:3 in English
Judges 5:3 · Berean Standard Bible
Listen, O kings! Give ear, O princes! I will sing to the LORD; I will sing praise to the LORD, the God of Israel.
Context
1Nígbà náà ni Debora àti Baraki ọmọ Abinoamu kọ orin ní ọjọ́ náà wí pé, 2“Nítorí bí àwọn olórí ti síwájú ní Israẹli,
nítorí bi àwọn ènìyàn ti fi tọkàntọkàn wa,
ẹ fi ìbùkún fún Olúwa! 3“Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọba! Ẹ fetí yín sílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ-aládé!
Èmi yóò kọrin sí Olúwa,
èmi yóò kọrin ìyìn sí Olúwa: Ọlọ́run Israẹli. 4“Olúwa nígbà tí o jáde kúrò ní Seiri,
nígbà tí ìwọ ń yan jáde wá láti pápá Edomu,
ilẹ̀ mì tìtì, àwọn ọ̀run sì kán sílẹ̀,
àní àwọsánmọ̀ pẹ̀lú kàn omi sílẹ̀. 5Àwọn òkè ńlá wárìrì ní iwájú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Sinai ní iwájú Olúwa
Ọlọ́run Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.