Onidajọ 4:10
Judges 4:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Baraki pe ẹ̀yà Sebuluni àti ẹ̀yà Naftali sí Kedeṣi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) akíkanjú ọkùnrin ogun tẹ̀lé e, Debora pẹ̀lú bá wọn lọ.
Judges 4:10 in English
Judges 4:10 · Berean Standard Bible
where he summoned Zebulun and Naphtali. Ten thousand men followed him, and Deborah also went with him.
Context
8Baraki sì dá a lóhùn pé, “Èmi yóò lọ tí ìwọ ó bá bá mi lọ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.” 9Debora dá a lóhùn pé, “ó dára, èmi yóò bá ọ lọ. Ṣùgbọ́n ọlá ìṣẹ́gun tí o ń lọ yìí kò ní jẹ́ tìrẹ, nítorí Olúwa yóò fi Sisera lé obìnrin lọ́wọ́,” báyìí Debora bá Baraki lọ sí Kedeṣi. 10Nígbà tí Baraki pe ẹ̀yà Sebuluni àti ẹ̀yà Naftali sí Kedeṣi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) akíkanjú ọkùnrin ogun tẹ̀lé e, Debora pẹ̀lú bá wọn lọ. 11Ǹjẹ́ Heberi ọmọ Keni, ti ya ara rẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Keni, àní àwọn ọmọ Hobabu, àna Mose, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ títí dé ibi igi óákù Saananimu, tí ó wà ni agbègbè Kedeṣi. 12Nígbà tí a sọ fún Sisera pé Baraki ọmọ Abinoamu ti kó ogun jọ sí òkè Tabori,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.