Onidajọ 3:2
Judges 3:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
(Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Israẹli tí kò rí ogun rí níbí a ti ṣe ń jagun).
Judges 3:2 in English
Judges 3:2 · Berean Standard Bible
if only to teach warfare to the subsequent generations of Israel, especially to those who had not known it formerly:
Context
1Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran tuntun ní Israẹli wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun àwọn ará Kenaani. 2(Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Israẹli tí kò rí ogun rí níbí a ti ṣe ń jagun). 3Àwọn ìjòyè ìlú Filistini márààrún, gbogbo àwọn ará Kenaani, àwọn ará Sidoni, àti àwọn ará Hifi tí ń gbé ní àwọn òkè Lebanoni bẹ̀rẹ̀ láti òkè Baali-Hermoni títí dé Lebo-Hamati. 4A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Israẹli wò bóyá wọn yóò gbọ́rọ̀ sí àwọn òfin Olúwa, èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipasẹ̀ Mose.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.