Onidajọ 3:12
Judges 3:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọmọ Israẹli sì tún padà sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì ṣe èyí tí ó burú ní iwájú Olúwa, fún ìdí iṣẹ́ búburú yìí, Olúwa fún Egloni, ọba àwọn Moabu ní agbára ní orí Israẹli.
Judges 3:12 in English
Judges 3:12 · Berean Standard Bible
Once again the Israelites did evil in the sight of the LORD. So He gave Eglon king of Moab power over Israel, because they had done evil in the sight of the LORD.
Context
10Ẹ̀mí Olúwa bà lé e, òun sì ṣe ìdájọ́ Israẹli, ó sì síwájú wọn lọ sí ogun. Olúwa sì fi Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu lé Otnieli lọ́wọ́, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ sì borí Kuṣani-Riṣataimu. 11Ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún títí tí Otnieli ọmọ Kenasi sì kú. 12Àwọn ọmọ Israẹli sì tún padà sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì ṣe èyí tí ó burú ní iwájú Olúwa, fún ìdí iṣẹ́ búburú yìí, Olúwa fún Egloni, ọba àwọn Moabu ní agbára ní orí Israẹli. 13Pẹ̀lú ìfi ọwọ́ ṣowọ́pọ̀ ogun àwọn Ammoni àti àwọn ọmọ-ogun Amaleki ní Egloni gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì gba ìlú Ọ̀pẹ tí i se Jeriko. 14Àwọn ọmọ Israẹli sì sin Egloni ọba Moabu fún ọdún méjìdínlógún.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.