Native Bible

Judges 21:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ibẹ̀, wọ́n lọ sí ilé àti ẹ̀yà rẹ̀ olúkúlùkù sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

Judges 21:24 in English

Judges 21:24 · Berean Standard Bible

And at that time, each of the Israelites returned from there to his own tribe and clan, each to his own inheritance.

Context

22Nígbà tí àwọn baba wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn bá fi ẹjọ́ sùn wá, àwa yóò wí fún wọn pé, ‘Ẹ ṣe wá ní oore nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́, nítorí àwa kò rí aya fún wọn ní àkókò ogun, ẹ̀yin kò sì ní jẹ̀bi, nítorí pé ẹ̀yin kọ́ ni ó fi àwọn ọmọbìnrin yín fún wọn bí aya.’ ” 23Èyí sì ni ohun tí àwọn ẹ̀yà Benjamini ṣe. Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin náà ń jó lọ́wọ́, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan mú ọmọbìnrin kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì gbé e lọ láti di aya rẹ̀. Wọ́n sì padà sí ilẹ̀ ìní wọn, wọ́n sì tún àwọn ìlú náà kọ́, wọ́n sì tẹ̀dó sínú wọn. 24Ní àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ibẹ̀, wọ́n lọ sí ilé àti ẹ̀yà rẹ̀ olúkúlùkù sí ilẹ̀ ìní rẹ̀. 25Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli; olúkúlùkù sì ń ṣe bí ó ti tọ́ ní ojú ara rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.