Native Bible

Judges 20:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ará Lefi náà, ọkọ obìnrin tí wọ́n pa fèsì pé, “Èmi àti àlè mi wá sí Gibeah ti àwọn ará Benjamini láti sùn di ilẹ̀ mọ́ níbẹ̀.

Judges 20:4 in English

Judges 20:4 · Berean Standard Bible

So the Levite, the husband of the murdered woman, answered: “I and my concubine came to Gibeah in Benjamin to spend the night.

Context

2Àwọn olórí gbogbo àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli dúró ní ipò wọn ní àpéjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ogún ọ̀kẹ́ (400,000) ọkùnrin ológun ti àwọn àti idà wọn. 3(Àwọn ẹ̀yà Benjamini gbọ́ wí pé àwọn ọmọ Israẹli yòókù ti gòkè lọ sí Mispa.) Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli wí pé, “Ẹ sọ fún wa báwo ni iṣẹ́ búburú ṣe ṣẹlẹ̀.” 4Ará Lefi náà, ọkọ obìnrin tí wọ́n pa fèsì pé, “Èmi àti àlè mi wá sí Gibeah ti àwọn ará Benjamini láti sùn di ilẹ̀ mọ́ níbẹ̀. 5Ṣùgbọ́n ní òru àwọn ọkùnrin Gibeah lépa mi wọ́n sì yí ilé náà po pẹ̀lú èrò láti pa mí. Wọ́n fi ipá bá àlè mi lòpọ̀, òun sì kú. 6Mo mú àlè mi náà, mo sì gé e sí ekìrí ekìrí, mo sì fi ekìrí kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí agbègbè ìní Israẹli kọ̀ọ̀kan, nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ àti ohun ìtìjú yìí ní ilẹ̀ Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.