Native Bible

Judges 20:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọkùnrin Israẹli àti àwọn tí o ba ní ibùba sínú igbó ti fún ara wọn ní àmì pé, kí àwọn tí ó ba ní ibùba fi èéfín ṣe ìkùùkuu ńlá láti inú ìlú náà,

Judges 20:38 in English

Judges 20:38 · Berean Standard Bible

The men of Israel had arranged a signal with the men in ambush: When they sent up a great cloud of smoke from the city,

Context

36Àwọn ẹ̀yà Benjamini sì rí pé wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn. Àwọn ọkùnrin Israẹli fàsẹ́yìn níwájú àwọn ẹ̀yà Benjamini nítorí pé wọ́n fọkàn tán àwọn tí ó wà ní ibùba ní ẹ̀bá Gibeah. 37Àwọn ọkùnrin tí wọ́n lúgọ yára jáde wọ́n sì tètè wọ Gibeah, wọ́n fọ́nká wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìlú náà. 38Àwọn ọkùnrin Israẹli àti àwọn tí o ba ní ibùba sínú igbó ti fún ara wọn ní àmì pé, kí àwọn tí ó ba ní ibùba fi èéfín ṣe ìkùùkuu ńlá láti inú ìlú náà, 39nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Israẹli yípadà, wọ́n sá gun. Àwọn ọmọ Benjamini sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun àti ní pípa àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó to ọgbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Àwa ń ṣẹ́gun wọn bí ìgbà ìjà àkọ́kọ́.” 40Ṣùgbọ́n nígbà tí ìkùùkuu èéfín bẹ̀rẹ̀ sí ní rú sókè láti inú ìlú náà wá, àwọn ẹ̀yà Benjamini yípadà wọ́n sì rí èéfín gbogbo ìlú náà ń gòkè sí ojú ọ̀run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.