Onidajọ 20:17
Judges 20:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọkùnrin Israẹli, yàtọ̀ sí àwọn ará Benjamini, ka ogún ọ̀kẹ́ (400,000) àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà.
Judges 20:17 in English
Judges 20:17 · Berean Standard Bible
The Israelites, apart from Benjamin, mobilized 400,000 swordsmen, each one an experienced warrior.
Context
15Ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ àwọn ará Benjamini kó ẹgbàá mẹ́tàlá (26,000) àwọn ọmọ-ogun tí ń lọ dájọ́ láti àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin nínú àwọn tí ń gbé Gibeah. 16Ní àárín àwọn ọmọ-ogun wọ̀nyí ni ó ti ní àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin tí wọ́n ń lo ọwọ́ òsì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dára dé bi pé wọ́n lè fi kànnàkànnà ba fọ́nrán òwú ní àìtàsé (wọ́n jẹ́ atamọ́tàsé). 17Àwọn ọkùnrin Israẹli, yàtọ̀ sí àwọn ará Benjamini, ka ogún ọ̀kẹ́ (400,000) àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà. 18Àwọn ọmọ Israẹli lọ sí Beteli, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Wọ́n wí pé, “Ta ni nínú wa tí yóò kọ́ kojú àwọn ará Benjamini láti bá wọn jà?”
Olúwa dáhùn pé, “Juda ni yóò kọ́ lọ.” 19Àwọn ọmọ Israẹli dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì dó ti Gibeah (wọ́n tẹ̀gùn sí ẹ̀bá Gibeah).
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.