Onidajọ 19:25
Judges 19:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà kò fetí sí tirẹ̀. Nítorí náà ọkùnrin náà mú àlè rẹ̀ ó sì tari rẹ̀ jáde sí wọn, wọ́n sì bá a fi ipá lòpọ̀, wọ́n sì fi gbogbo òru náà bá a lòpọ̀, nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́.
Judges 19:25 in English
Judges 19:25 · Berean Standard Bible
But the men would not listen to him. So the Levite took his concubine and sent her outside to them, and they raped her and abused her throughout the night, and at dawn they let her go.
Context
23Ọkùnrin, baálé ilé náà sì jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ má ṣe hùwà búburú; nítorí tí ọkùnrin yìí ti wọ ilé mi, ẹ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí. 24Kíyèsi i, ọmọbìnrin mi ni èyí, wúńdíá, àti àlè rẹ̀; àwọn ni èmi ó mú jáde wá nísinsin yìí, kí ẹ̀yin tẹ̀ wọ́n lógo, kí ẹ̀yin ṣe sí wọn bí ó ti tọ́ lójú yín: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí ni kí ẹ̀yin má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí sí.” 25Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà kò fetí sí tirẹ̀. Nítorí náà ọkùnrin náà mú àlè rẹ̀ ó sì tari rẹ̀ jáde sí wọn, wọ́n sì bá a fi ipá lòpọ̀, wọ́n sì fi gbogbo òru náà bá a lòpọ̀, nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́. 26Nígbà tí ojúmọ́ bẹ̀rẹ̀ sí là obìnrin náà padà lọ sí ilé tí ọ̀gá rẹ̀ wà, ó ṣubú lulẹ̀ lọ́nà, ó sì wà níbẹ̀ títí ó fi di òwúrọ̀. 27Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ jí tí ó sì dìde ní òwúrọ̀ tí ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ilé náà, tí ó sì bọ́ sí òde láti tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, kíyèsi i àlè rẹ̀ wà ní ṣíṣubú ní iwájú ilé, tí ọwọ́ rẹ̀ sì di òpó ẹnu-ọ̀nà ibẹ̀ mú,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.