Onidajọ 19:18
Judges 19:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọmọ Lefi náà dá a lóhùn pé, “Bẹtilẹhẹmu ti Juda ni àwa ti ń bọ̀, àwa sì ń lọ sí agbègbè tí ó sá pamọ́ ní àwọn òkè Efraimu níbi ti mo ń gbé. Mo ti lọ sí Bẹtilẹhẹmu ti Juda, èmi sì ń lọ sí ilé Olúwa nísinsin yìí. Kò sí ẹni tí ó gbà mí sí ilé rẹ̀.
Judges 19:18 in English
Judges 19:18 · Berean Standard Bible
The Levite replied, “We are traveling from Bethlehem in Judah to the remote hill country of Ephraim, where I am from. I went to Bethlehem in Judah, and now I am going to the house of the LORD;* but no one has taken me into his home,
Context
16Ní alẹ́ ọjọ́ náà ọkùnrin arúgbó kan láti àwọn òkè Efraimu, ṣùgbọ́n tí ń gbé ní Gibeah (ibẹ̀ ni àwọn ẹ̀yà Benjamini ń gbé) ń ti ibi iṣẹ́ rẹ̀ bọ̀ láti inú oko. 17Nígbà tí ó wòkè ó rí arìnrìn-àjò náà ní gbọ̀ngàn ìlú náà, ọkùnrin arúgbó yìí bi í léèrè pé, “Níbo ni ò ń lọ? Níbo ni o ti ń bọ̀?” 18Ọmọ Lefi náà dá a lóhùn pé, “Bẹtilẹhẹmu ti Juda ni àwa ti ń bọ̀, àwa sì ń lọ sí agbègbè tí ó sá pamọ́ ní àwọn òkè Efraimu níbi ti mo ń gbé. Mo ti lọ sí Bẹtilẹhẹmu ti Juda, èmi sì ń lọ sí ilé Olúwa nísinsin yìí. Kò sí ẹni tí ó gbà mí sí ilé rẹ̀. 19Àwa ní koríko àti oúnjẹ tó tó fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa àti oúnjẹ àti wáìnì fún àwa ìránṣẹ́ rẹ—èmi, ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú wa. A ò ṣe aláìní ohun kankan.” 20Ọkùnrin arúgbó náà sì wí pé. “Àlàáfíà fún ọ, bí ó ti wù kí ó rí, èmi yóò pèsè gbogbo ohun tí o nílò, kìkì pé kí ìwọ má ṣe sun ní ìgboro.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.