Native Bible

Judges 19:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì Israẹli kò ní ọba. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Lefi tí ń gbé ibi tí ó sá pamọ́ nínú àwọn agbègbè òkè Efraimu, mú àlè kan láti Bẹtilẹhẹmu ní Juda.

Judges 19:1 in English

Judges 19:1 · Berean Standard Bible

Now in those days, when there was no king in Israel, a Levite who lived in the remote hill country of Ephraim took for himself a concubine from Bethlehem in Judah.

Context

1Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì Israẹli kò ní ọba. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Lefi tí ń gbé ibi tí ó sá pamọ́ nínú àwọn agbègbè òkè Efraimu, mú àlè kan láti Bẹtilẹhẹmu ní Juda. 2Ṣùgbọ́n àlè rẹ̀ náà sì ṣe panṣágà sí i, òun fi sílẹ̀, ó sì padà lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Bẹtilẹhẹmu ti Juda, ó sì wà ní ibẹ̀ ní ìwọ̀n oṣù mẹ́rin, 3ọkọ rẹ̀ lọ sí ibẹ̀ láti rọ̀ ọ́ pé kí ó padà sí ọ̀dọ̀ òun. Nígbà tí ó ń lọ ó mú ìránṣẹ́ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì lọ́wọ́, obìnrin náà mú un wọ inú ilé baba rẹ̀ lọ, nígbà tí baba obìnrin náà rí i ó fi tayọ̀tayọ̀ gbà á.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.