Native Bible

Judges 18:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àlùfáà náà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà. Ìrìnàjò yín tí ẹ̀yin ń rìn bá ojúrere Olúwa pàdé.”

Judges 18:6 in English

Judges 18:6 · Berean Standard Bible

And the priest told them, “Go in peace. The LORD is watching over your journey.”

Context

4Ó sọ ohun tí Mika ti ṣe fún un, ó fi kún un fún wọn pé, “Ó gbà mí sí iṣẹ́, èmi sì ni àlùfáà rẹ̀.” 5Wọ́n wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ béèrè ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí àwa lè mọ̀ bí ìrìnàjò wa yóò yọrí sí rere.” 6Àlùfáà náà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà. Ìrìnàjò yín tí ẹ̀yin ń rìn bá ojúrere Olúwa pàdé.” 7Àwọn ọkùnrin márààrún náà kúrò, wọ́n sì wá sí Laiṣi, níbi tí wọ́n ti rí i pé àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ ní ààbò, bí àwọn ará Sidoni, láìsí ìfòyà àti ní ìpamọ́. Ní ìgbà tí ilẹ̀ wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, wọ́n ní ọrọ̀ púpọ̀. Ibùgbé wọn tún jìnnà sí ti àwọn ará Sidoni, wọn kò fi ohunkóhun bá ẹnikẹ́ni dàpọ̀. 8Nígbà tí wọ́n padà sí Sora àti Eṣtaoli, àwọn arákùnrin wọn bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni ibi tí ẹ lọ ti rí? Kí ni ìròyìn tí ẹ mú wá?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.