Native Bible

Judges 18:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì jáde lọ, ní ojú ọ̀nà wọn, wọ́n tẹ̀dó ogun sí ẹ̀bá Kiriati-Jearimu ní Juda. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń gbé ìwọ̀-oòrùn Kiriati-Jearimu ni Mahane-Dani títí di òní yìí.

Judges 18:12 in English

Judges 18:12 · Berean Standard Bible

They went up and camped at Kiriath-jearim in Judah. That is why the place west of Kiriath-jearim is called Mahaneh-dan * to this day.

Context

10Nígbà tí ẹ̀yin bá dé ibẹ̀, ẹ yóò rí àwọn ènìyàn tí ọkàn wọn balẹ̀ àti ilẹ̀ tí ó tẹ́jú tí Ọlọ́run ti fi fún yín, ilẹ̀ tí kò ṣe aláìní nǹkan kan.” 11Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin tí ó múra ogun láti ìran Dani, jáde lọ láti Sora àti Eṣtaoli ní mímú ra láti jagun. 12Wọ́n sì jáde lọ, ní ojú ọ̀nà wọn, wọ́n tẹ̀dó ogun sí ẹ̀bá Kiriati-Jearimu ní Juda. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń gbé ìwọ̀-oòrùn Kiriati-Jearimu ni Mahane-Dani títí di òní yìí. 13Láti ibẹ̀ wọ́n kọjá lọ sí àwọn ìlú agbègbè òkè Efraimu, wọ́n sì dé ilé Mika. 14Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin márùn-ún tí ó lọ yọ́ ilẹ̀ Laiṣi wò sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ọ̀kan nínú àwọn ilé yìí ní ẹ̀wù efodu, àwọn yòókù ní òrìṣà, ère gbígbẹ́ àti ère dídà? Ẹ mọ ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe báyìí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.