Onidajọ 16:27
Judges 16:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní àsìkò náà, tẹmpili yìí kún fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin; gbogbo àwọn ìjòyè Filistini wà níbẹ̀, ní òkè ilé náà, níbi tí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ń wòran Samsoni bí òun ti ń ṣeré.
Judges 16:27 in English
Judges 16:27 · Berean Standard Bible
Now the temple was full of men and women; all the lords of the Philistines were there, and about three thousand men and women were on the roof watching Samson entertain them.
Context
25Nígbà tí inú wọn dùn gidigidi tí wọ́n ń yọ ayọ̀ ńlá, wọ́n pariwo pé, ẹ mú Samsoni wá kí ó wá dá wa lára yá. Wọ́n sì pe Samsoni jáde láti ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, òun sì ń ṣeré fún wọn.
Nígbà tí wọ́n mú un dúró láàrín àwọn òpó. 26Samsoni sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó di ọwọ́ rẹ̀ mú pé, “Ẹ fi mí si ibi tí ọwọ́ mi yóò ti le tó àwọn òpó tí ó gbé tẹmpili dúró mú, kí èmi lè fẹ̀yìn tì wọ́n.” 27Ní àsìkò náà, tẹmpili yìí kún fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin; gbogbo àwọn ìjòyè Filistini wà níbẹ̀, ní òkè ilé náà, níbi tí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ń wòran Samsoni bí òun ti ń ṣeré. 28Nígbà náà ni Samsoni ké pe Olúwa wí pé, “Olúwa Olódùmarè, rántí mi. Háà Ọlọ́run jọ̀wọ́ fi agbára fún mi lẹ́ẹ̀kan yìí sí i, kí èmi lè gbẹ̀san lára àwọn Filistini nítorí àwọn ojú mi méjèèjì.” 29Samsoni sì na ọwọ́ mú àwọn òpó méjèèjì tí ó wà láàrín gbùngbùn, orí àwọn tí tẹmpili náà dúró lé, ó fi ọwọ́ ọ̀tún mú ọ̀kan àti ọwọ́ òsì mú èkejì, ó fi ara tì wọ́n,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.