Native Bible

Judges 16:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dẹlila sì sọ fún Samsoni pé, ìwọ ti tàn mí; o sì purọ́ fún mi. Wá báyìí kí o sì sọ bí a ti ṣe le dè ọ́.

Judges 16:10 in English

Judges 16:10 · Berean Standard Bible

Then Delilah said to Samson, “You have mocked me and lied to me! Now please tell me how you can be tied up.”

Context

8Àwọn olóyè Filistini sì mú okùn tútù méje tí ẹnikẹ́ni kò sá gbẹ wá fún Dẹlila òun sì fi wọ́n dè é. 9Nígbà tí àwọn ènìyàn tí sá pamọ́ sínú yàrá, òun pè pé, “Samsoni àwọn Filistini ti dé láti mú ọ.” Ṣùgbọ́n òun já àwọn okùn náà bí òwú ti í já nígbà tí ó bá wà lẹ́bàá iná. Torí náà wọn kò mọ àṣírí agbára rẹ̀. 10Dẹlila sì sọ fún Samsoni pé, ìwọ ti tàn mí; o sì purọ́ fún mi. Wá báyìí kí o sì sọ bí a ti ṣe le dè ọ́. 11Òun dáhùn pé, “Bí wọ́n bá lè fi okùn tuntun tí ẹnikẹ́ni kò tí ì lò rí dì mí dáradára, èmi yóò di aláìlágbára, èmi yóò sì dàbí àwọn ọkùnrin yòókù.” 12Dẹlila sì mú àwọn okùn tuntun, ó fi wọ́n dì í. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Filistini ti fi ara pamọ́ sínú yàrá, òun kígbe sí i pé, “Samsoni àwọn Filistini dé láti mú ọ,” òun sì já okùn náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀ bí òwú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.