Onidajọ 15:8
Judges 15:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó kọlù wọ́n pẹ̀lú ìbínú àti agbára ńlá, ó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn. Lẹ́yìn náà ni ó lọ, ó sì dúró nínú ihò àpáta kan nínú àpáta Etamu.
Judges 15:8 in English
Judges 15:8 · Berean Standard Bible
And he struck them ruthlessly * with a great slaughter, and then went down and stayed in the cave at the rock of Etam.
Context
6Nígbà tí àwọn Filistini béèrè pé, “Ta ni ó ṣe èyí?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni ará Timna ni, nítorí a gba ìyàwó rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.”
Nítorí náà àwọn Filistini lọ wọ́n sì sun obìnrin náà àti baba rẹ̀. 7Samsoni sọ fún un pé, “Nítorí pé ẹ̀yin ṣe èyí, èmi ó gbẹ̀san lára yín, lẹ́yìn náà èmi yóò sì dẹ́kun.” 8Ó kọlù wọ́n pẹ̀lú ìbínú àti agbára ńlá, ó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn. Lẹ́yìn náà ni ó lọ, ó sì dúró nínú ihò àpáta kan nínú àpáta Etamu. 9Àwọn ará Filistini sì dìde ogun sí Juda, wọ́n ti tan ara wọn ká sí agbègbè Lehi. 10Àwọn ọkùnrin Juda sì béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ fi wá gbóguntì wá?”
Ìdáhùn wọn ni pé, “A wá láti mú Samsoni ní ìgbèkùn, kí a ṣe sí i bí òun ti ṣe sí wa.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.