Onidajọ 15:1
Judges 15:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè alikama, Samsoni mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan láti bẹ ìyàwó rẹ̀ wò. Ó ní, “Èmi yóò wọ yàrá ìyàwó mi lọ.” Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà á láààyè láti wọlé.
Judges 15:1 in English
Judges 15:1 · Berean Standard Bible
Later on, at the time of the wheat harvest, Samson took a young goat and went to visit his wife. “I want to go to my wife in her room,” he said. But her father would not let him enter.
Context
1Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè alikama, Samsoni mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan láti bẹ ìyàwó rẹ̀ wò. Ó ní, “Èmi yóò wọ yàrá ìyàwó mi lọ.” Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà á láààyè láti wọlé. 2Baba ìyàwó dá a lóhùn pé, “Ó dá mi lójú pé o kórìíra rẹ̀, torí náà mo ti fi fún ọ̀rẹ́ rẹ, ṣe bí àbúrò rẹ̀ obìnrin kò ha lẹ́wà jùlọ? Fẹ́ ẹ dípò rẹ̀.” 3Samsoni dáhùn pé, “Ní àkókò yìí tí mo bá ṣe àwọn Filistini ní ibi èmi yóò jẹ́ aláìjẹ̀bi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.