Native Bible

Judges 14:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn èyí, ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára. Ó lọ sí Aṣkeloni, ó pa ọgbọ̀n nínú àwọn ọkùnrin wọn, ó gba àwọn ohun ìní wọn, ó sì fi àwọn aṣọ wọn fún àwọn tí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà. Ó sì padà sí ilé baba rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú ríru.

Judges 14:19 in English

Judges 14:19 · Berean Standard Bible

Then the Spirit of the LORD came mightily upon him, and he went down to Ashkelon, killed thirty of their men, took their apparel, and gave their clothes to those who had solved the riddle. And burning with anger, Samson returned to his father’s house,

Context

17Fún gbogbo ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣe àsè náà ni ó fi sọkún, nítorí náà ní ọjọ́ keje ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ fún un nítorí pé ó yọ ọ́ lẹ́nu ní ojoojúmọ́. Òun náà sì sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ènìyàn rẹ̀. 18Kí ó tó di àṣálẹ́ ọjọ́ keje àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún un pé, “Kí ni ó dùn ju oyin lọ? Kí ni ó sì lágbára ju kìnnìún lọ?” Samsoni dá wọn lóhùn pé, “Bí kì í bá ṣe pé ẹ fi ọ̀dọ́ abo màlúù mi kọ ilẹ̀, ẹ̀yin kò bá tí mọ ìtumọ̀ sí àlọ́ mi.” 19Lẹ́yìn èyí, ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára. Ó lọ sí Aṣkeloni, ó pa ọgbọ̀n nínú àwọn ọkùnrin wọn, ó gba àwọn ohun ìní wọn, ó sì fi àwọn aṣọ wọn fún àwọn tí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà. Ó sì padà sí ilé baba rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú ríru. 20Wọ́n sì fi ìyàwó Samsoni fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ rẹ̀ nígbà ìgbéyàwó rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.