Native Bible

Judges 13:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni obìnrin náà tọ ọkọ rẹ̀ lọ, o sì sọ fún un wí pé, “Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ mí wá. Ó jọ angẹli Ọlọ́run, ó ba ènìyàn lẹ́rù gidigidi. Èmi kò béèrè ibi tí ó ti wá, òun náà kò sì sọ orúkọ rẹ̀ fún mi.

Judges 13:6 in English

Judges 13:6 · Berean Standard Bible

So the woman went and told her husband, “A man of God came to me. His appearance was like the angel of God, exceedingly awesome. I did not ask him where he came from, and he did not tell me his name.

Context

4Báyìí rí i dájúdájú pé ìwọ kò mu wáìnì tàbí ọtí líle kankan àti pé ìwọ kò jẹ ohun aláìmọ́ kankan, 5nítorí ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Má ṣe fi abẹ kan orí rẹ̀, nítorí pé Nasiri, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀. Òun ni yóò bẹ̀rẹ̀ ìdáǹdè àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Filistini.” 6Nígbà náà ni obìnrin náà tọ ọkọ rẹ̀ lọ, o sì sọ fún un wí pé, “Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ mí wá. Ó jọ angẹli Ọlọ́run, ó ba ènìyàn lẹ́rù gidigidi. Èmi kò béèrè ibi tí ó ti wá, òun náà kò sì sọ orúkọ rẹ̀ fún mi. 7Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi wí pé, ‘Ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, fún ìdí èyí, má ṣe mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ má ṣe jẹ ohunkóhun tí í ṣe aláìmọ́, nítorí pé Nasiri Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.’ ” 8Nígbà náà ni Manoa gbàdúrà sí Olúwa wí pé, “Háà Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run tí ìwọ rán sí wa padà tọ̀ wá wá láti kọ́ wa bí àwa yóò ti ṣe tọ́ ọmọ tí àwa yóò bí náà.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.