Onidajọ 13:23
Judges 13:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ìyàwó rẹ̀ dáhùn pé, “Bí Olúwa bá ní èrò àti pa wá kò bá tí gba ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wa, tàbí fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn wá tó sọ nǹkan ìyanu yìí fún wa.”
Judges 13:23 in English
Judges 13:23 · Berean Standard Bible
But his wife replied, “If the LORD had intended to kill us, He would not have accepted the burnt offering and the grain offering from our hands, nor would He have shown us all these things or spoken to us this way.”
Context
21Nígbà tí angẹli Olúwa náà kò tún fi ara rẹ̀ han Manoa àti aya rẹ̀ mọ́, Manoa wá mọ̀ pé angẹli Olúwa ni. 22Manoa sọ fún aya rẹ̀ pé, “Dájúdájú àwa yóò kú nítorí àwa ti fi ojú rí Ọlọ́run.” 23Ṣùgbọ́n ìyàwó rẹ̀ dáhùn pé, “Bí Olúwa bá ní èrò àti pa wá kò bá tí gba ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wa, tàbí fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn wá tó sọ nǹkan ìyanu yìí fún wa.” 24Obìnrin náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Samsoni. Ọmọ náà dàgbà Olúwa sì bùkún un. 25Ẹ̀mí Olúwa sì bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nígbà tí ó wà ní Mahane-Dani ní agbede-méjì Sora àti Eṣtaoli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.