Onidajọ 13:16
Judges 13:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Angẹli Olúwa náà dá Manoa lóhùn pé, “Bí ẹ̀yin tilẹ̀ dá mi dúró, èmi kì yóò jẹ ọ̀kankan nínú oúnjẹ tí ẹ̀yin yóò pèsè. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá fẹ́ ẹ pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sí Olúwa.” (Manoa kò mọ̀ pé angẹli Olúwa ní i ṣe.)
Judges 13:16 in English
Judges 13:16 · Berean Standard Bible
And the angel of the LORD replied, “Even if I stay, I will not eat your food. But if you prepare a burnt offering, offer it to the LORD.” For Manoah did not know that it was the angel of the LORD.
Context
14kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti inú èso àjàrà jáde wá, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn tàbí jẹ ohunkóhun tí ó bá jẹ́ aláìmọ́. Ó ní láti ṣe ohun gbogbo tí mo ti pàṣẹ fún un.” 15Manoa sọ fún angẹli Olúwa náà pé, “Jọ̀wọ́ dára dúró títí àwa yóò fi pèsè ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan fún ọ.” 16Angẹli Olúwa náà dá Manoa lóhùn pé, “Bí ẹ̀yin tilẹ̀ dá mi dúró, èmi kì yóò jẹ ọ̀kankan nínú oúnjẹ tí ẹ̀yin yóò pèsè. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá fẹ́ ẹ pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sí Olúwa.” (Manoa kò mọ̀ pé angẹli Olúwa ní i ṣe.) 17Manoa sì béèrè lọ́wọ́ angẹli Olúwa náà pé, “Kí ni orúkọ rẹ, kí àwa bá à lè fi ọlá fún ọ nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ?” 18Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa náà dáhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ ń béèrè orúkọ mi? Ìyanu ni, ó kọjá ìmọ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.