Onidajọ 1:8
Judges 1:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ológun Juda sì ṣẹ́gun Jerusalẹmu, wọ́n sì kó o, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì dáná sun ìlú náà.
Judges 1:8 in English
Judges 1:8 · Berean Standard Bible
Then the men of Judah fought against Jerusalem and captured it. They put the city to the sword and set it on fire.
Context
6Ọba Adoni-Beseki sá àsálà, ṣùgbọ́n ogun Israẹli lépa rẹ̀ wọ́n sì bá a, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀. 7Nígbà náà ni Adoni-Beseki wí pé, “Àádọ́rin ọba ni èmi ti gé àtàǹpàkò wọn tí wọ́n sì ń ṣa èérún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Báyìí Ọlọ́run ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo ṣe sí wọn.” Wọ́n sì mú un wá sí Jerusalẹmu, ó sì kú síbẹ̀. 8Àwọn ológun Juda sì ṣẹ́gun Jerusalẹmu, wọ́n sì kó o, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì dáná sun ìlú náà. 9Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ogun Juda sọ̀kalẹ̀ lọ láti bá àwọn ará Kenaani tí ń gbé ní àwọn ìlú orí òkè ní gúúsù àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ òkè lápá ìwọ̀-oòrùn Juda jagun. 10Ogun Juda sì tún ṣígun tọ ará Kenaani tí ń gbé Hebroni (tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiriati-Arba) ó sì ṣẹ́gun Ṣeṣai, Ahimani àti Talmai.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.