Native Bible

Judges 1:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ẹ̀yà Naftali pẹ̀lú kò lé àwọn ará Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati jáde; ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Naftali náà ń gbé àárín àwọn ará Kenaani tí ó ti ní ilẹ̀ náà rí, ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbé Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati ń sìn ìsìn tipátipá.

Judges 1:33 in English

Judges 1:33 · Berean Standard Bible

Naphtali failed to drive out the inhabitants of Beth-shemesh and Beth-anath. So the Naphtalites also lived among the Canaanite inhabitants of the land, but the inhabitants of Beth-shemesh and Beth-anath served them as forced laborers.

Context

31Bẹ́ẹ̀ ni Aṣeri kò lé àwọn tí ń gbé ní Akko tàbí ní Sidoni tàbí ní Ahlabu tàbí ní Aksibu tàbí ní Helba tàbí ní Afiki tàbí ní Rehobu. 32Ṣùgbọ́n nítorí àwọn ará Aṣeri ń gbé láàrín àwọn ará Kenaani tí wọ́n ni ilẹ̀ náà. 33Àwọn ẹ̀yà Naftali pẹ̀lú kò lé àwọn ará Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati jáde; ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Naftali náà ń gbé àárín àwọn ará Kenaani tí ó ti ní ilẹ̀ náà rí, ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbé Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati ń sìn ìsìn tipátipá. 34Àwọn ará Amori fi agbára dá àwọn ẹ̀yà Dani dúró sí àwọn ìlú orí òkè, wọn kò sì jẹ́ kí wọn sọ̀kalẹ̀ wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀. 35Àwọn ará Amori ti pinnu láti dúró lórí òkè Heresi àti òkè Aijaloni àti ti Ṣaalbimu, ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yà Josẹfu di alágbára wọ́n borí Amori wọ́n sì mú wọn sìn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.