Native Bible

Judges 1:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Sebuluni kò lé àwọn ará Kenaani tí ń gbé Kitironi jáde tàbí àwọn ará Nahalali, ṣùgbọ́n wọ́n sọ wọ́n di ẹrú. Wọ́n sì ń sin àwọn ará Sebuluni.

Judges 1:30 in English

Judges 1:30 · Berean Standard Bible

Zebulun failed to drive out the inhabitants of Kitron and Nahalol; so the Canaanites lived among them and served as forced laborers.

Context

28Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli di alágbára, wọ́n mú àwọn ará Kenaani sìn bí i ẹrú, ṣùgbọ́n wọn kò fi agbára lé wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ náà. 29Efraimu náà kò lé àwọn ará Kenaani tí ó ń gbé Geseri jáde, ṣùgbọ́n àwọn ará Kenaani sì ń gbé láàrín àwọn ẹ̀yà Efraimu. 30Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Sebuluni kò lé àwọn ará Kenaani tí ń gbé Kitironi jáde tàbí àwọn ará Nahalali, ṣùgbọ́n wọ́n sọ wọ́n di ẹrú. Wọ́n sì ń sin àwọn ará Sebuluni. 31Bẹ́ẹ̀ ni Aṣeri kò lé àwọn tí ń gbé ní Akko tàbí ní Sidoni tàbí ní Ahlabu tàbí ní Aksibu tàbí ní Helba tàbí ní Afiki tàbí ní Rehobu. 32Ṣùgbọ́n nítorí àwọn ará Aṣeri ń gbé láàrín àwọn ará Kenaani tí wọ́n ni ilẹ̀ náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.