Onidajọ 1:22
Judges 1:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ẹ̀yà Josẹfu sì bá Beteli jagun, Olúwa síwájú pẹ̀lú wọn.
Judges 1:22 in English
Judges 1:22 · Berean Standard Bible
The house of Joseph also attacked Bethel, and the LORD was with them.
Context
20Gẹ́gẹ́ bí Mose ti ṣèlérí, wọ́n fún Kalebu ní Hebroni, ó sì lé àwọn tí ń gbé ibẹ̀ kúrò; àwọn náà ni ìran àwọn ọmọ Anaki mẹ́ta. 21Àwọn ẹ̀yà Benjamini ni wọn kò le lé àwọn Jebusi tí wọ́n ń gbé Jerusalẹmu, nítorí náà wọ́n ń gbé àárín àwọn Israẹli títí di òní. 22Àwọn ẹ̀yà Josẹfu sì bá Beteli jagun, Olúwa síwájú pẹ̀lú wọn. 23Nígbà tí ẹ̀yà Josẹfu rán àwọn ènìyàn láti lọ yọ́ Beteli wò (orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí ni Lusi). 24Àwọn ayọ́lẹ̀wò náà rí ọkùnrin kan tí ń jáde láti inú ìlú náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ọ̀nà àtiwọ ìlú yìí hàn wá, àwa ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí, a ó sì ṣe àánú fún ọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.