Onidajọ 1:11
Judges 1:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Láti ibẹ̀, wọ́n sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Debiri (tí à ń pè ní Kiriati-Seferi nígbà kan rí).
Judges 1:11 in English
Judges 1:11 · Berean Standard Bible
From there they marched against the inhabitants of Debir (formerly known as Kiriath-sepher).
Context
9Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ogun Juda sọ̀kalẹ̀ lọ láti bá àwọn ará Kenaani tí ń gbé ní àwọn ìlú orí òkè ní gúúsù àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ òkè lápá ìwọ̀-oòrùn Juda jagun. 10Ogun Juda sì tún ṣígun tọ ará Kenaani tí ń gbé Hebroni (tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiriati-Arba) ó sì ṣẹ́gun Ṣeṣai, Ahimani àti Talmai. 11Láti ibẹ̀, wọ́n sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Debiri (tí à ń pè ní Kiriati-Seferi nígbà kan rí). 12Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.” 13Otnieli ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu sì gbà á, báyìí ni Kalebu sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Aksa fún un ní ìyàwó.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.