Native Bible

James 5:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Inú ẹnikẹ́ni ha bàjẹ́ nínú yín bí? Jẹ́ kí ó gbàdúrà. Inú ẹnikẹ́ni ha dùn? Jẹ́ kí ó kọrin mímọ́.

James 5:13 in English

James 5:13 · Berean Standard Bible

Is any one of you suffering? He should pray. Is anyone cheerful? He should sing praises.

Context

11Sá à wò ó, àwa a máa ka àwọn tí ó fi ara dà ìyà sí ẹni ìbùkún. Ẹ̀yin ti gbọ́ ti sùúrù Jobu, ẹ̀yin sì rí ìgbẹ̀yìn tí Olúwa ṣe; pé Olúwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú. 12Ṣùgbọ́n ju ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ má ṣe ìbúra, ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, tàbí ilẹ̀, tàbí ìbúra-kíbúra mìíràn. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí “Bẹ́ẹ̀ ni” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni; àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ẹ má ba à bọ́ sínú ẹ̀bi. 13Inú ẹnikẹ́ni ha bàjẹ́ nínú yín bí? Jẹ́ kí ó gbàdúrà. Inú ẹnikẹ́ni ha dùn? Jẹ́ kí ó kọrin mímọ́. 14Ẹnikẹ́ni ha ṣe àìsàn nínú yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ìjọ, kí wọ́n sì gbàdúrà sórí rẹ̀, kí wọn fi òróró kùn ún ní orúkọ Olúwa. 15Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì gba aláìsàn náà là, Olúwa yóò sì gbé e dìde; bí ó bá sì ṣe pé ó ti dẹ́ṣẹ̀, a ó dáríjì í.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.