Native Bible

James 4:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin béèrè, ẹ kò sì rí gbà, nítorí tí ẹ̀yin ṣì béèrè, kí ẹ̀yin kí ó lè lò ó fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín.

James 4:3 in English

James 4:3 · Berean Standard Bible

And when you do ask, you do not receive, because you ask with wrong motives, that you may squander it on your pleasures.

Context

1Níbo ni ogun ti wá, níbo ni ìjà sì ti wá láàrín yín? Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín ha kọ́ ni tí ó ń jagun nínú àwọn ẹ̀yà ara yín bí? 2Ẹ̀yin ń fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ẹ kò sì ní, ẹ̀yin ń pànìyàn, ẹ sì ń ṣe ìlara, ẹ kò sì le ní: ẹ̀yin ń jà, ẹ̀yin sì ń jagun; ẹ kò ní, nítorí tí ẹ̀yin kò béèrè. 3Ẹ̀yin béèrè, ẹ kò sì rí gbà, nítorí tí ẹ̀yin ṣì béèrè, kí ẹ̀yin kí ó lè lò ó fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín. 4Ẹ̀yin panṣágà ọkùnrin, àti panṣágà obìnrin, ẹ kò mọ̀ pé ìbárẹ́ ayé ìṣọ̀tá Ọlọ́run ni? Nítorí náà ẹni tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé di ọ̀tá Ọlọ́run. 5Ẹ̀yin ṣe bí Ìwé Mímọ́ sọ lásán pé, Ẹ̀mí tí ó fi sínú wa ń jowú gidigidi lórí wa?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.