Native Bible

James 3:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí olúkúlùkù ẹ̀dá ẹranko, àti ti ẹyẹ, àti ti ejò, àti ti ohun tí ó ń bẹ ní Òkun, ni à ń tù lójú, tí a sì ti tù lójú láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn wá.

James 3:7 in English

James 3:7 · Berean Standard Bible

All kinds of animals, birds, reptiles, and creatures of the sea are being tamed and have been tamed by man,

Context

5Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà kékeré, ó sì ń fọhùn ohùn ńlá. Wo igi ńlá tí iná kékeré ń sun jóná! 6Iná sì ni ahọ́n, ayé ẹ̀ṣẹ̀ sì ni: ní àárín àwọn ẹ̀yà ara wa, ní ahọ́n ti ń bá gbogbo ara jẹ́, tí yóò sì ti iná bọ ipa ayé wa; ọ̀run àpáàdì a sì tiná bọ òun náà. 7Nítorí olúkúlùkù ẹ̀dá ẹranko, àti ti ẹyẹ, àti ti ejò, àti ti ohun tí ó ń bẹ ní Òkun, ni à ń tù lójú, tí a sì ti tù lójú láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn wá. 8Ṣùgbọ́n ahọ́n ni ẹnikẹ́ni kò le tù lójú; ohun búburú aláìgbọ́ràn ni, ó kún fún oró ikú tí í pa ni. 9Òun ni àwa fi ń yin Olúwa àti Baba, òun ni a sì fi ń bú ènìyàn tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.