Native Bible

James 2:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

tí ẹ̀yin sì bu ọlá fún ẹni tí ó wọ aṣọ dáradára tí ẹ sì wí pé, “Ìwọ jókòó níhìn-ín yìí ní ibi dáradára,” tí ẹ sì wí fún tálákà náà pé, “Ìwọ dúró níbẹ̀” tàbí “jókòó níhìn-ín lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi,”

James 2:3 in English

James 2:3 · Berean Standard Bible

If you lavish attention on the man in fine clothes and say, “Here is a seat of honor,” but say to the poor man, “You must stand” or “Sit at my feet,”

Context

1Ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́ nínú ògo Olúwa wá Jesu Kristi, ẹ máa ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni. 2Nítorí bí ọkùnrin kan bá wá sí ìpéjọpọ̀ yín, pẹ̀lú òrùka wúrà àti aṣọ dáradára, tí tálákà kan sì wá pẹ̀lú nínú aṣọ èérí; 3tí ẹ̀yin sì bu ọlá fún ẹni tí ó wọ aṣọ dáradára tí ẹ sì wí pé, “Ìwọ jókòó níhìn-ín yìí ní ibi dáradára,” tí ẹ sì wí fún tálákà náà pé, “Ìwọ dúró níbẹ̀” tàbí “jókòó níhìn-ín lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi,” 4ẹyin kò ha ń dá ara yín sí méjì nínú ara yín, ẹ̀yin kò sì di onídàájọ́ tí ó ní èrò búburú bí? 5Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́: Ọlọ́run kò ha ti yan àwọn tálákà ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́, àti ajogún ìjọba náà, tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.