Native Bible

James 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò ṣe aláìní ohunkóhun.

James 1:4 in English

James 1:4 · Berean Standard Bible

Allow perseverance to finish its work, so that you may be mature and complete, not lacking anything.

Context

2Ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdánwò, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀; 3nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìdánwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣiṣẹ́ sùúrù. 4Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò ṣe aláìní ohunkóhun. 5Bí ó bá ku ọgbọ́n fún ẹnikẹ́ni, kí ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ẹni tí fi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí kì í sì ka àlébù sí; a ó sì fi fún un. 6Ṣùgbọ́n nígbà tí òun bá béèrè ní ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì rárá. Nítorí ẹni tí ó ń sé iyèméjì dàbí ìgbì omi Òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn, tí a sì ń rú u sókè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.