Native Bible

James 1:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìbùkún ni fún ọkùnrin tí ó fi ọkàn rán ìdánwò; nítorí nígbà tí ó bá yege, yóò gba adé ìyè, tí Olúwa ti ṣèlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ.

James 1:12 in English

James 1:12 · Berean Standard Bible

Blessed is the man who perseveres under trial, because when he has stood the test, he will receive the crown of life that God has promised to those who love Him.

Context

10Àti ọlọ́rọ̀, ní ìrẹ̀sílẹ̀, nítorí bí ìtànná koríko ni yóò kọjá lọ. 11Nítorí oòrùn là ti òun ti ooru gbígbóná yóò gbẹ́ koríko, ìtànná rẹ̀ sì rẹ̀ dànù, ẹwà ojú rẹ̀ sì parun: bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ọlọ́rọ̀ yóò ṣègbé ní ọ̀nà rẹ̀. 12Ìbùkún ni fún ọkùnrin tí ó fi ọkàn rán ìdánwò; nítorí nígbà tí ó bá yege, yóò gba adé ìyè, tí Olúwa ti ṣèlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ. 13Kí ẹnikẹ́ni tí a dánwò kí ó má ṣe wí pé, “Láti ọwọ́ Ọlọ́run ni a ti dán mi wò.” Nítorí a kò lè fi búburú dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnikẹ́ni wò; 14ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni a ń dánwò nígbà tí a bá fi ọwọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ fà á lọ tí a sì tàn án jẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.