Isaiah 8:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn náà, mo lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin náà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Olúwa sì wí fún mi pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Maha-Ṣalali-Haṣi-Basi.
Isaiah 8:3 in English
Isaiah 8:3 · Berean Standard Bible
And I had relations with the prophetess, and she conceived and gave birth to a son. The LORD said to me, “Name him Maher-shalal-hash-baz.
Context
1Olúwa sọ fún mi pé, mú ìwé ńlá kan, kí o sì fi kálàmù ìkọ̀wé lásán kọ Maha-Ṣalali-Haṣi-Basi. 2Èmi yóò sì mú Uriah àlùfáà àti Sekariah ọmọ Jeberekiah gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí òtítọ́ wá sí ọ̀dọ̀ mi. 3Lẹ́yìn náà, mo lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin náà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Olúwa sì wí fún mi pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Maha-Ṣalali-Haṣi-Basi. 4Kí ọmọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń sọ pé, ‘Baba mi’ tàbí ‘Ìyá mi,’ gbogbo ọrọ̀ Damasku àti ìkógun ti Samaria ni ọba àwọn Asiria yóò ti kó lọ.” 5Olúwa sì tún sọ fún mi pé,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.