Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah jẹ́ ọba Juda, ọba Resini ti Aramu àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá láti bá Jerusalẹmu jà, ṣùgbọ́n wọn kò sì le è borí i rẹ̀.

Isaiah 7:1 in English

Isaiah 7:1 · Berean Standard Bible

Now in the days that Ahaz son of Jotham, the son of Uzziah, was king of Judah, Rezin king of Aram * marched up to wage war against Jerusalem. He was accompanied by Pekah son of Remaliah the king of Israel, but he could not overpower the city.

Context

1Nígbà tí Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah jẹ́ ọba Juda, ọba Resini ti Aramu àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá láti bá Jerusalẹmu jà, ṣùgbọ́n wọn kò sì le è borí i rẹ̀. 2Báyìí, a sọ fún ilé Dafidi pé, “Aramu mà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Efraimu”; fún ìdí èyí, ọkàn Ahasi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ wárìrì gẹ́gẹ́ bí igi oko ṣe ń wárìrì níwájú afẹ́fẹ́. 3Lẹ́yìn èyí, Olúwa sọ fún Isaiah pé, “Jáde, ìwọ àti ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ Ṣeari-Jaṣubu láti pàdé Ahasi ní ìpẹ̀kun ìṣàn omi ti adágún òkè, ní òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí pápá Alágbàfọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.