Isaiah 50:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tanná tí ẹ sì ń fi pèsè iná ìléwọ́ fún ara yín, ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín, àti nínú ẹta iná tí ẹ ti dá. Èyí ni yóò jẹ́ tiyín láti ọwọ́ mi wá. Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìrora.
Isaiah 50:11 in English
Isaiah 50:11 · Berean Standard Bible
Behold, all you who kindle a fire, who array yourselves with firebrands, walk in the light of your fire and of the firebrands you have lit! This is what you will receive from My hand: You will lie down in a place of torment.
Context
9Olúwa Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́.
Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi?
Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ;
kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run. 10Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù Olúwa
tí ó sì ń gbọ́rọ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu?
Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùn
tí kò ní ìmọ́lẹ̀,
kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa
kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀. 11Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tanná
tí ẹ sì ń fi pèsè iná ìléwọ́ fún ara yín,
ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín,
àti nínú ẹta iná tí ẹ ti dá.
Èyí ni yóò jẹ́ tiyín láti ọwọ́ mi wá.
Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìrora.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.