Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òun jókòó lórí ìtẹ́ ní òkè òbírí ilẹ̀ ayé, àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata. Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà, ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé.

Isaiah 40:22 in English

Isaiah 40:22 · Berean Standard Bible

He sits enthroned above the circle of the earth; its dwellers are like grasshoppers. He stretches out the heavens like a curtain, and spreads them out like a tent to dwell in.

Context

20Ọkùnrin kan tí ó tálákà jù kí ó lè mú irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá, wá igi tí kò le è rà. Ó wá oníṣọ̀nà tí ó láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú. 21Ǹjẹ́ o kò tí ì mọ̀ ìwọ kò tí ì gbọ́? A kò tí ì sọ fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá? Ìwọ kò tí ì mọ láti ìgbà ìpìlẹ̀ ayé? 22Òun jókòó lórí ìtẹ́ ní òkè òbírí ilẹ̀ ayé, àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata. Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà, ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé. 23Ó sọ àwọn ọmọ ọba di asán àti àwọn aláṣẹ ayé yìí ni ó ti sọ dòfo. 24Gẹ́rẹ́ tí a ti gbìn wọ́n, kété tí a gbìn wọ́n, kété tí wọ́n fi gbòǹgbò múlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n gbogbo wọn sì gbẹ, bẹ́ ni ìjì líle sì gbá wọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.