Isaiah 37:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohun tí ọba Asiria ti ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó pa wọ́n run pátápátá. Ǹjẹ́ a ó ha dá ọ nídè bí?
Isaiah 37:11 in English
Isaiah 37:11 · Berean Standard Bible
Surely you have heard what the kings of Assyria have done to all the other countries, devoting them to destruction.* Will you then be spared?
Context
9Ní àkókò yìí Sennakeribu gbọ́ ìròyìn kan pé Tirakah ará Kuṣi ọba Ejibiti ń jáde bọ̀ wá bá òun jà. Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, 10“Ẹ sọ fún Hesekiah ọba Juda pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ nígbà tí ó sọ pé, ‘A kì yóò jọ̀wọ́ Jerusalẹmu fún ọba Asiria.’ 11Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohun tí ọba Asiria ti ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó pa wọ́n run pátápátá. Ǹjẹ́ a ó ha dá ọ nídè bí? 12Ǹjẹ́ àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun ha gbà wọ́n sílẹ̀ bí àwọn òrìṣà Gosani, Harani, Reṣefu àti àwọn ènìyàn Edeni tí wọ́n wà ní Teli-Assari? 13Níbo ni ọba Hamati wà, ọba Arpadi, ọba ìlú Sefarfaimi tàbí Hena tàbí Iffa?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.