Isaiah 24:21
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò jẹ ẹ́ ní yà gbogbo agbára tí ó wà lókè lọ́run àti àwọn ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé.
Isaiah 24:21 in English
Isaiah 24:21 · Berean Standard Bible
In that day the LORD will punish the host of heaven above and the kings of the earth below.
Context
19Ilẹ̀ ayé ti fọ́
ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù,
a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì. 20Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí,
ó bì síwá sẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́;
ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rù
tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́. 21Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò jẹ ẹ́ ní yà
gbogbo agbára tí ó wà lókè lọ́run
àti àwọn ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé. 22A ó sì kó wọn jọ pọ̀,
gẹ́gẹ́ bí ará túbú jọ sínú ihò,
a ó tì wọ́n mọ́ inú túbú,
a ó sì bẹ̀ wọ́n wò lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́. 23A ó rẹ òṣùpá sílẹ̀, ojú yóò sì ti oòrùn;
nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ ọba
ní orí òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu,
àti níwájú àwọn àgbàgbà rẹ ní ògo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.