Isaiah 20:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ní àkókò náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa ti ẹnu Isaiah ọmọ Amosi jáde. Ó sọ fún un pé, “Mú aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò ní ara rẹ kí o sì bọ́ sálúbàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà.
Isaiah 20:2 in English
Isaiah 20:2 · Berean Standard Bible
the LORD had already spoken through Isaiah son of Amoz, saying, “Go, remove the sackcloth from your waist and the sandals from your feet.” And Isaiah did so, walking around naked and barefoot.
Context
1Ní ọdún tí olórí ogun, tí Sagoni ọba Asiria rán an, wá sí Aṣdodu, ó kọlù ú ó sì kó o— 2ní àkókò náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa ti ẹnu Isaiah ọmọ Amosi jáde. Ó sọ fún un pé, “Mú aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò ní ara rẹ kí o sì bọ́ sálúbàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà. 3Lẹ́yìn náà ni Olúwa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ mi Isaiah ti lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí àmì àti àpẹẹrẹ sí Ejibiti àti Kuṣi, 4bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọba Asiria yóò kó àwọn ìgbèkùn Ejibiti lọ ní ìhòhò àti láì wọ bàtà pẹ̀lú àwọn àtìpó Kuṣi, ọ̀dọ́ àti àgbà, pẹ̀lú ìbàdí ìhòhò—bí àbùkù Ejibiti.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.