Isaiah 14:22
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èmi yóò dìde sókè sí wọn,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Babeli àti àwọn tí ó sálà, àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀,” ni Olúwa wí.
Isaiah 14:22 in English
Isaiah 14:22 · Berean Standard Bible
“I will rise up against them,” declares the LORD of Hosts. “I will cut off from Babylon her name and her remnant, her offspring and her posterity,” declares the LORD.
Context
20a kò ní sin ọ́ pẹ̀lú wọn,
nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́
o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ.
Ìran àwọn ìkà
ni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́. 21Tọ́jú ibìkan tí a ó ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹ
nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn,
wọn kò gbọdọ̀ dìde láti jogún ilẹ̀
kí wọ́n sì bo orí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlú u wọn. 22“Èmi yóò dìde sókè sí wọn,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
“Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Babeli àti àwọn tí ó sálà,
àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀,”
ni Olúwa wí. 23Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwí
àti sí irà;
Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a,
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 24Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra,
“Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí,
àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.