Isaiah 11:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù tí ó kù sílẹ̀ ní Asiria, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Israẹli nígbà tí wọ́n gòkè láti Ejibiti wá.
Isaiah 11:16 in English
Isaiah 11:16 · Berean Standard Bible
There will be a highway for the remnant of His people who remain from Assyria, as there was for Israel when they came up from the land of Egypt.
Context
14Wọn yóò fò mọ́ èjìká Filistini
sí apá ìwọ̀-oòrùn,
wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọn
ènìyàn apá ìlà-oòrùn.
Wọn yóò gbé ọwọ́ wọn lé Edomu àti Moabu,
àwọn ará Ammoni yóò sì di ìwẹ̀fà wọn. 15Olúwa yóò sọ di gbígbé
àyasí Òkun Ejibiti,
pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ rẹ̀,
kọjá lórí odò Eufurate.
Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méje
tó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn
yóò máa là á kọjá pẹ̀lú bàtà. 16Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù
tí ó kù sílẹ̀ ní Asiria,
gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Israẹli
nígbà tí wọ́n gòkè láti Ejibiti wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.