Isaiah 1:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Màlúù mọ olówó rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀, ṣùgbọ́n Israẹli kò mọ̀, òye kò yé àwọn ènìyàn mi.”
Isaiah 1:3 in English
Isaiah 1:3 · Berean Standard Bible
The ox knows its owner, and the donkey its master’s manger, but Israel does not know; My people do not understand.”
Context
1Ìran sí Juda àti Jerusalẹmu èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí ní àsìkò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah àwọn ọba Juda. 2Gbọ́ ẹ̀yin ọ̀run! Fi etí sílẹ̀, ìwọ ayé!
Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀:
“Mo tọ́ àwọn ọmọ dàgbà,
ṣùgbọ́n wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi. 3Màlúù mọ olówó rẹ̀,
kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀,
ṣùgbọ́n Israẹli kò mọ̀,
òye kò yé àwọn ènìyàn mi.” 4Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,
àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù,
ìran àwọn aṣebi,
àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́!
Wọn ti kọ Olúwa sílẹ̀
wọn ti gan Ẹni Mímọ́ Israẹli,
wọn sì ti kẹ̀yìn sí i. 5Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́?
Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe?
Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́,
gbogbo ọkàn yín sì ti pòruurù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.