Hosea 2:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò bẹ̀ ọjọ́ Baalimu wò ní ara rẹ̀ nínú èyí tó ń fi tùràrí jóná fún Baali; tí ó fi òrùka etí àti ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, tó sì tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n èmi ni òun gbàgbé,” ni Olúwa wí.
Hosea 2:13 in English
Hosea 2:13 · Berean Standard Bible
I will punish her for the days of the Baals when she burned incense to them, when she decked herself with rings and jewelry, and went after her lovers. But Me she forgot,” declares the LORD.
Context
11Èmi yóò mú gbogbo ayọ̀ rẹ̀ wá sí òpin:
àjọ̀dún ọdọọdún rẹ̀, oṣù tuntun rẹ̀,
ọjọ́ ìsinmi, àti gbogbo àwọn àjọ̀dún tí a yàn. 12Èmi yóò pa àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ run,
èyí tí ó pè ní èrè rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀,
Èmi yóò sọ wọ́n di igbó,
àwọn ẹranko búburú yóò sì jẹ́ wọn run. 13Èmi yóò bẹ̀ ọjọ́ Baalimu wò ní ara rẹ̀
nínú èyí tó ń fi tùràrí jóná fún Baali;
tí ó fi òrùka etí àti ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́,
tó sì tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ.
Ṣùgbọ́n èmi ni òun gbàgbé,”
ni Olúwa wí. 14“Nítorí náà, èmi yóò tàn án,
Èmi ó sì mú u lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀,
Èmi ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀ 15Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un,
Èmi yóò fi àfonífojì Akori ṣe ìlẹ̀kùn ìrètí fún un.
Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Ejibiti.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.