Hosea 2:1
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ, ‘Ènìyàn mi,’ kí o sì wí fún àwọn arábìnrin rẹ ‘Àyànfẹ́ mi.’
Hosea 2:1 in English
Hosea 2:1 · Berean Standard Bible
“Say of your brothers, ‘My people,’* and of your sisters, ‘My loved one.’*
Context
1“Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ, ‘Ènìyàn mi,’ kí o sì wí fún àwọn arábìnrin rẹ ‘Àyànfẹ́ mi.’ 2“Ẹ bá ìyá yín wí, ẹ bá a wí,
nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi,
Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀.
Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀
àti àìṣòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀. 3Àìṣe bẹ́ẹ̀ èmi yóò tú u sí ìhòhò,
Èmi yóò sì gbé e kalẹ̀ bí ọjọ́ tí a bí i.
Èmi yóò ṣe ọ́ bí i aṣálẹ̀ ilẹ̀,
Èmi yóò sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀
Èmi yóò sì fi òǹgbẹ gbẹ ẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.