Heberu 9:25
Hebrews 9:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kì í sí i ṣe pé kí ó lè máa fi ara rẹ̀ rú ẹbọ nígbàkígbà, bí olórí àlùfáà tí máa ń wọ inú Ibi Mímọ́ Jùlọ lọ lọ́dọọdún ti òun pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ti kì í ṣe tirẹ̀,
Hebrews 9:25 in English
Hebrews 9:25 · Berean Standard Bible
Nor did He enter heaven to offer Himself again and again, as the high priest enters the Most Holy Place every year with blood that is not his own.
Context
23Nítorí náà a kò lè ṣàì fi ìwọ̀nyí wé àwọn àpẹẹrẹ ohun tí ń bẹ lọ́run mọ́; ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ju ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run pàápàá mọ́; ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ju ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run pàápàá mọ́. 24Nítorí Kristi kò wọ ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ ṣe lọ tí i ṣe àpẹẹrẹ ti òtítọ́; ṣùgbọ́n ó lọ sí ọ̀run pàápàá, nísinsin yìí láti farahàn ní iwájú Ọlọ́run fún wa. 25Kì í sí i ṣe pé kí ó lè máa fi ara rẹ̀ rú ẹbọ nígbàkígbà, bí olórí àlùfáà tí máa ń wọ inú Ibi Mímọ́ Jùlọ lọ lọ́dọọdún ti òun pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ti kì í ṣe tirẹ̀, 26bí bẹ́ẹ̀ bá ni, òun ìbá tí máa jìyà nígbàkígbà láti ìpìlẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ni ó fi ara hàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lópin ayé láti mu ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípa ẹbọ ara rẹ̀. 27Níwọ́n bí a sì ti fi lélẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí ìdájọ́,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.