Native Bible

Hebrews 9:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ọmọ màlúù, ṣùgbọ́n nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkára rẹ̀, o wọ Ibi Mímọ́ Jùlọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, lẹ́yìn tí ó ti rí ìdáǹdè àìnípẹ̀kun gbà fún wa.

Hebrews 9:12 in English

Hebrews 9:12 · Berean Standard Bible

He did not enter by the blood of goats and calves, but He entered the Most Holy Place once for all by His own blood, thus securing eternal redemption.

Context

10Èyí sì wà nínú ohun jíjẹ àti ohun mímu àti onírúurú ìwẹ̀, tí í ṣe ìlànà ti ara nìkan tí a fi lélẹ̀ títí fi di ìgbà àtúnṣe. 11Ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi dé bí olórí àlùfáà àwọn ohun rere tí ń bọ̀, nípasẹ̀ àgọ́ tí o tóbi ti ó sì pé ju ti ìṣáájú, èyí tí a kò fi ọwọ́ dá, èyí yìí ni, tí kì í ṣe ti ẹ̀dá yìí. 12Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ọmọ màlúù, ṣùgbọ́n nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkára rẹ̀, o wọ Ibi Mímọ́ Jùlọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, lẹ́yìn tí ó ti rí ìdáǹdè àìnípẹ̀kun gbà fún wa. 13Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti akọ màlúù àti eérú ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí a ti sọ di aláìmọ́ ba ń sọ ni di mímọ́ fún ìwẹ̀nùmọ́ ara: 14mélòó mélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹni, nípa Ẹ̀mí ayérayé, tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ sí Ọlọ́run láìní àbàwọ́n, yóò wẹ èérí ọkàn yín nù kúrò nínú òkú iṣẹ́ láti sin Ọlọ́run alààyè?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.