Native Bible

Hebrews 8:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ìbá ṣe pé májẹ̀mú ìṣáájú nì kò ní àbùkù, ǹjẹ́ a kì bá ti wá ààyè fún èkejì.

Hebrews 8:7 in English

Hebrews 8:7 · Berean Standard Bible

For if that first covenant had been without fault, no place would have been sought for a second.

Context

5Àwọn ẹni tí ń jọ́sìn nínú pẹpẹ kan tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ àti òjìji ohun tí ń bẹ ní ọ̀run. Ìdí abájọ nìyí tí a fi kìlọ̀ fún Mose nígbà tí ó fẹ́ kọ́ àgọ́, nítorí ó wí pé, “Kíyèsí i, kí ìwọ kí ó ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ wọn, ti a fi hàn ọ́ ni orí òkè.” 6Ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó ni ọlá jù, níwọ̀n bí o ti jẹ pé alárinà májẹ̀mú tí o dára jù ní i ṣe, èyí tí a fi ṣe òfin lórí ìlérí tí o sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ. 7Nítorí ìbá ṣe pé májẹ̀mú ìṣáájú nì kò ní àbùkù, ǹjẹ́ a kì bá ti wá ààyè fún èkejì. 8Nítorí tí ó rí àbùkù lára wọn, ó wí pé, “Ìgbà kan ń bọ̀, ni Olúwa wí, tí Èmi yóò bá ilé Israẹli àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun. 9Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú tí mo ti bá àwọn baba baba wọn dá, nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, nítorí wọn kò jẹ́ olóòtítọ́ sí májẹ̀mú mi èmi kò sì ta wọ́n nu, ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.